Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Suburbs

4 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà náà, wọn yóò ní ìlú tí wọn yóò gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn, ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú gbogbo ìní wọn.

  2. “Ilẹ̀ pápá oko tútù káàkiri ìlú tí ẹ ó fi fún àwọn ọmọ Lefi, wíwọ̀n rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ (1,500 ẹsẹ̀ bàtà) láti ògiri ìlú náà.

  3. Lẹ́yìn ìlú náà, wọn ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́ lápá ibi ìhà ìlà-oòrùn, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹsẹ̀ bàtà ní ìhà gúúsù, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà ìwọ̀-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ní ìhà àríwá, kí ìlú náà sì wà ní àárín. Wọn yóò ní agbègbè yìí gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ pápá oko tútù fún ìlú náà.

  4. Àwọn ọmọ Josẹfu sì di ẹ̀yà méjì, Manase àti Efraimu. Àwọn ọmọ Lefi kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.