Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Simplicity: In preaching the gospel
Àwọn ẹsẹ nípa In preaching the gospel
Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.
Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.
A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.
A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín.
Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀,