Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rehum

7 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jerusalẹmu sí Artasasta ọba báyìí:

  2. Rehumu balógun àti Ṣimṣai akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tókù—àwọn ará Dina, ti Afarsatki, ti Tarpeli, ti Afarsi, Ereki àti Babeli, àwọn ará Elamu ti Susa,

  3. Ọba fi èsì yìí ránṣẹ́ padà. Sí Rehumu balógun, Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí ń gbé ní Samaria àti ní òpópónà Eufurate. Ìkíni.

  4. Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Artasasta sí Rehumu àti Ṣimṣai akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jerusalẹmu pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.

  5. Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Lefi, ní abẹ́ ẹ Rehumu ọmọ Bani. Lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni Haṣabiah, alákòóso ìdajì agbègbè Keila ṣe àtúnṣe fún agbègbè tirẹ̀.

  6. Rehumu, Haṣabna, Maaseiah,

  7. Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,