Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rashness
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé, “Èké ni gbogbo ènìyàn”.
Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀, ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn.
Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
Ètè àwọn olóye jásí èrè bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.
Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?
Ǹjẹ́ ó rí ènìyàn tí ń kánjú sọ̀rọ̀? Ìrètí wà fún aláìgbọ́n jù ú lọ.
Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ, má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run. Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run ìwọ sì wà ní ayé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n.
Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.