Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Pretorium
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gómìnà mú Jesu lọ sí gbọ̀ngàn ìdájọ́ wọ́n sì kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tì í.
Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Pretoriomu), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ.
Nígbà náà, wọ́n fa Jesu láti ọ̀dọ̀ Kaiafa lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́, ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkára wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá.
Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”
Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn.
Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.
Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi.