Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Merab

4 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Àwọn ọmọ Saulu sì ni Jonatani, Iṣifi àti Malikiṣua. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Merabu àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Mikali.

  2. Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.”

  3. Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?”

  4. Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya.