- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Menstruation: Law relating to
Àwọn ẹsẹ nípa Law relating to
“ ‘Bí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, obìnrin yìí wà ní àìmọ́ títí di ọjọ́ méje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
“ ‘Gbogbo ohun tí ó bá sùn lé ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ di àìmọ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ibùsùn rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó bá jókòó lé gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
Ìbá à ṣe ibùsùn tàbí ohunkóhun tí ó jókòó lé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá a lòpọ̀, tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ibùsùn tí ọkùnrin náà bá sùn yóò jẹ́ aláìmọ́.
“ ‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀.
Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá jókòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́. Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
“ ‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́.
Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
“ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn.
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli, ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.