Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Melita: An island in the Mediterranean. Paul shipwrecked on the coast of.
Àwọn ẹsẹ nípa An island in the Mediterranean. Paul shipwrecked on the coast of.
Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà.
Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa. Nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.
Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.”
Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.
Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì; nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pubiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.
Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.