Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Girdle

13 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù efodu méjèèjì ní ìsàlẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó súnmọ́ ojú sí ìránṣọ náà, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu náà.

  2. Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù efodu pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù efodu náà.

  3. Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.”

  4. Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

  5. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì,

  6. “Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.”

  7. Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

  8. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.”

  9. Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

  10. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:

  11. “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu.

  12. Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun.

  13. Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’