Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ethanim: Day of Atonement, on the tenth day of
Àwọn ẹsẹ nípa Day of Atonement, on the tenth day of
Olúwa sọ fún Mose pé,
“Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.
Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”