Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Dream: Delusive
Àwọn ẹsẹ nípa Delusive
Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá òkè Sioni jà.