Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Darkness

6 ẹsẹ · 39 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

  2. Kí òkùnkùn àti òjìji ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọsánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdudu ọjọ́ kí ó pa láyà.

  3. Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí a má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

  4. Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.

  5. Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn ún kí o fi gégùn ún, tí wọ́n mura tán láti ru Lefitani sókè.

  6. Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn; kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀mọ́júmọ́