Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Anointing of the Holy Spirit

7 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

  2. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

  3. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

  4. Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.

  5. Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.

  6. Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.

  7. Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.