Fò sí àkóónú

the giant in Gath

7 ẹsẹ · 5 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan the giant in Gath

  1. Iṣbi-Benobu sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Rafa, ẹni tí ọ̀kọ̀ rẹ̀ wọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì idẹ, ó sì sán idà tuntun, ó sì gbèrò láti pa Dafidi.

  2. Lẹ́yìn èyí, ìjà kan sì tún wà láàrín àwọn Israẹli àti àwọn Filistini ní Gobu, nígbà náà ni Sibekai ará Huṣati pa Safu, ẹni tí í ṣe ọ̀kan nínú àwọn Rafa.

  3. Ìjà kan sì tún wà ní Gati, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹsẹ̀ mẹ́fà ní ẹsẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní Rafa.

  4. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni ìran Rafa ní Gati, wọ́n sì ti ọwọ́ Dafidi ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

  5. Ní ẹ̀yìn èyí ni ogun bẹ́ sílẹ̀ ní Geseri pẹ̀lú àwọn ará Filistini, ní àkókò yìí ni Sibekai ará Huṣati pa Sipai, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Refaimu, àti àwọn ará Filistini ni a ṣẹ́gun.

  6. Síbẹ̀síbẹ̀ nínú ogun mìíràn, tí ó wáyé ní Gati, ọkùnrin títóbi kan wà tí ó ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìka mẹ́fà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rìnlélógún lápapọ̀. Òun pẹ̀lú wá láti Rafa.

  7. Wọ̀nyí ni ìran ọmọ Rafa ní Gati, wọ́n sì ṣubú sí ọwọ́ Dafidi àti àwọn ọkùnrin rẹ̀.