Skip to content

Jonadab

7 ẹsẹ · 1 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jonathan

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jonadab

  1. Ṣùgbọ́n Amnoni ní ọ̀rẹ́ kan, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Jonadabu, ọmọ Ṣimea ẹ̀gbọ́n Dafidi, Jonadabu sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn gidigidi.

  2. Jonadabu sì wí fún un pé, “Dùbúlẹ̀ ní ibùsùn rẹ kí ìwọ sì díbọ́n pé, ìwọ kò sàn, baba rẹ yóò sì wá wò ọ́, ìwọ ó sì wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí Tamari àbúrò mi wá kí ó sì fún mi ní oúnjẹ kí ó sì ṣe oúnjẹ náà níwájú mi kí èmi ó rí i, èmi ó sì jẹ ẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀.’ ”

  3. Jonadabu ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì dáhùn ó sì wí pé, “Kí olúwa mi ọba má ṣe rò pé wọ́n ti pa gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin àwọn ọmọ ọba; nítorí pé Amnoni nìkan ṣoṣo ni ó kú, nítorí láti ẹnu Absalomu wá ni a ti pinnu rẹ̀ láti ọjọ́ tí ó ti fi agbára mú Tamari àbúrò rẹ̀.

  4. Jonadabu sì wí fún ọba pé, “Wò ó, àwọn ọmọ ọba ń bọ́; gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí.”

  5. Nígbà tí òun sì pe Israẹli ní ìjà. Jonatani ọmọ Ṣimea arákùnrin Dafidi sì pa á.

  6. Nígbà tí ó fi Israẹli ṣẹ̀sín, Jonatani ọmọ Ṣimea, arákùnrin Dafidi sì pa á.

  7. Jonatani, arákùnrin Dafidi jẹ́ olùdámọ̀ràn, ọkùnrin onímọ̀ àti akọ̀wé. Jehieli ọmọ Hakmoni bojútó àwọn ọmọ ọba.