Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trust: Blessedness of placing, in God
Àwọn ẹsẹ nípa Blessedness of placing, in God
Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú, kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín, nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan. Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.
Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára; ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
Ayọ̀ ni fún àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé wọn tí wọn kò sì yípadà sí agbéraga, tàbí àwọn tí ó yapa lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́run mìíràn.
“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.