Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Agriculture or Husbandry: Storing in barns
Àwọn ẹsẹ nípa Storing in barns
Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?
Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì máa dàgbà pọ̀, títí di àsìkò ìkórè. Èmi yóò sọ fún àwọn olùkórè náà láti kọ́kọ́ ṣa àwọn èpò kúrò kí wọ́n sì dìwọ́n ní ìtí, kí a sì sun wọn, kí wọ́n sì kó alikama sínú àká mi.’ ”