Skip to content
Sekariah 1:11-21

Sekariah 1:11-21

11
Wọ́n si dá angẹli Olúwa tí ó dúró láàrín àwọn igi maritili náà lóhùn pé, “Àwa ti rìn sókè sódò já ayé, àwa sí ti rí i pé gbogbo ayé wà ní ìsinmi àti àlàáfíà.”
12
Nígbà náà ni angẹli Olúwa náà dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ kì yóò fi ṣàánú fún Jerusalẹmu, àti fún àwọn ìlú ńlá Juda, ti ìwọ ti bínú sí ni àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”
13
Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ ìtùnú dá angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn.
14
Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni.
15
Èmi sì bínú púpọ̀púpọ̀ si àwọn orílẹ̀-èdè tí ó rò wí pé òun ní ààbò. Nítorí nígbà tí mo bínú díẹ̀, wọ́n ran ìparun lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú.’
16
“Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí: ‘Mo padà tọ Jerusalẹmu wá pẹ̀lú àánú; ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, a ó kọ́ ilé mi sínú rẹ̀, a o sí ta okùn ìwọ̀n kan jáde sórí Jerusalẹmu.’
17
“Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”
18
Mo si gbé ojú sókè, mo sì rí, sì kíyèsi i, ìwo mẹ́rin.
19
Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni nǹkan wọ̀nyí?” Ó si dà mí lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọ̀nyí ni ó tí tú Juda, Israẹli, àti Jerusalẹmu ká.”
20
Olúwa sì fi alágbẹ̀dẹ mẹ́rin kan hàn mí.
21
Nígbà náà ni mo wí pé, “Kí ni àwọn wọ̀nyí wá ṣe?” O sì sọ wí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni ìwo tí ó ti tú Juda ká, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò fi gbé orí rẹ̀ sókè? Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wá láti dẹ́rùbà wọ́n, láti lé ìwo àwọn orílẹ̀-èdè jáde, ti wọ́n gbé ìwo wọn sórí ilẹ̀ Juda láti tú ènìyàn rẹ̀ ká.”

Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.

Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options