Skip to content
Orin Solomoni 4:1-7

Orin Solomoni 4:1-7

1
Báwo ni ìwọ ti lẹ́wà tó olólùfẹ́ mi! Háà, ìwọ jẹ́ arẹwà! Ìwọ ní ojú àdàbà lábẹ́ ìbòjú rẹ irun rẹ bò ọ́ lójú bí ọ̀wọ́ ewúrẹ́. Tí ó sọ̀kalẹ̀ lórí òkè Gileadi.
2
Eyín rẹ̀ funfun bí i irun àgbò tí ó gòkè wá láti ibi ìwẹ̀; olúkúlùkù wọn bí èjìrẹ́; kò sí ọ̀kan nínú wọn tí ó da dúró.
3
Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó; ẹnu rẹ̀ dùn. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ẹ̀là pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ.
4
Ọrùn rẹ dàbí ilé ìṣọ́ Dafidi, tí a kọ́ pẹ̀lú ìhámọ́ra; lórí rẹ̀ ni a fi ẹgbẹ̀rún (1,000) àpáta kọ́, gbogbo wọn jẹ́ àṣà àwọn alágbára.
5
Ọmú rẹ̀ méjèèjì dàbí abo egbin méjì tí wọ́n jẹ́ ìbejì tí ń jẹ láàrín ìtànná ewéko lílì.
6
Títí ọjọ́ yóò fi rọ̀ tí òjìji yóò fi fò lọ, èmi yóò lọ sí orí òkè ńlá òjìá àti sí òkè kékeré tùràrí.
7
Gbogbo ara rẹ jẹ́ kìkì ẹwà, olólùfẹ́ mi; kò sì ṣí àbàwọ́n lára rẹ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options