Orin Solomoni 5:2-8
2
Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”
3
Mo ti bọ́ aṣọ ìgúnwà mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún gbé e wọ̀? Mo ti wẹ ẹsẹ̀ mi ṣé èmi gbọdọ̀ tún tì í bọ eruku?
4
Olùfẹ́ mi na ọwọ́ rẹ̀ láti inú ihò ìlẹ̀kùn inú mi sì yọ́ sí i.
5
Èmi dìde láti ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, òjìá bẹ̀rẹ̀ sí í kán ní ọwọ́ mi, òjìá olóòórùn ń ti ara ìka mi ń sàn sí orí ìdìmú ìlẹ̀kùn.
6
Èmi ṣí ìlẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi, ṣùgbọ́n olùfẹ́ mi ti kúrò, ó ti lọ ọkàn mi gbọgbẹ́ fún lílọ rẹ̀. Mo wá a kiri ṣùgbọ́n, n kò rí i. Mo pè é ṣùgbọ́n, kò dáhùn.
7
Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi bí wọ́n ti ṣe ń rìn yí ìlú ká. Wọ́n nà mí, wọ́n sá mi lọ́gbẹ́; wọ́n gba ìborùn mi lọ́wọ́ mi. Àwọn olùṣọ́ tí ń ṣọ́ odi!
8
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, mo bẹ̀ yín bí ẹ̀yin bá rí olùfẹ́ mi, kí ni ẹ̀yin yóò wí fún un? Ẹ wí fún un pé àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mi.
Settings