Ìfihàn 19:19-21
19
Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun.
20
A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó.
21
Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde, gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.
Settings