Saamu 78:12-29
12
Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ Ejibiti, ní agbègbè Ṣoani.
13
Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga.
14
Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná.
15
Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá.
16
Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.
17
Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18
Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.
19
Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20
Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”
21
Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22
nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23
Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24
Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25
Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26
Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27
Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun
28
Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn.
29
Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.
Settings