Skip to content
Saamu 78:17-33

Saamu 78:17-33

17
Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18
Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún.
19
Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20
Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”
21
Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22
nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23
Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24
Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25
Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26
Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27
Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun
28
Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn.
29
Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún.
30
Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn,
31
ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.
32
Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.
33
O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options