Saamu 73:12-22
12
Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí, ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.
13
Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́; nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14
Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu; a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.
15
Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,” èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16
Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí, Ó jẹ́ ìnilára fún mi,
17
títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run; nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.
18
Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́ ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19
Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan! Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20
Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí, bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa, ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.
21
Nígbà tí inú mi bàjẹ́ àti ọkàn mi ṣì korò,
22
mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye; mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.
Settings