Skip to content
Saamu 51:1-9

Saamu 51:1-9

1
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba. Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3
Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi, nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4
Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀, kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀, kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
5
Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú; ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
7
Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́; fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
8
Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn; jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9
Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options