Saamu 119:153-160
153
Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ.
154
Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.
155
Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ.
156
Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, Olúwa; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
157
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ.
158
Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́.
159
Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ.
160
Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni.
Settings