Saamu 119:145-152
145
Èmi kígbe pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: dá mi lóhùn Olúwa, èmi yóò sì gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ.
146
Èmi kígbe pè ọ́; gbà mí èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́.
147
Èmi dìde ṣáájú àfẹ̀mọ́júmọ́ èmi ké fún ìrànlọ́wọ́; èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
148
Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.
149
Gbọ́ ohùn mi ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ: pa ayé mi mọ́, Olúwa, gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ.
150
Àwọn tí ń gbìmọ̀ ìlànà búburú wà ní tòsí, ṣùgbọ́n wọ́n jìnnà sí òfin rẹ.
151
Síbẹ̀ ìwọ wà ní tòsí, Olúwa, àti gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òtítọ́.
152
Láti ọjọ́ pípẹ́ wá èmi ti kọ́ nínú òfin rẹ tí ìwọ ti fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé.
Settings