Filipi 2:25-30
25
Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi.
26
Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn.
27
Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́.
28
Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù.
29
Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa; kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.
30
Nítorí iṣẹ́ Kristi ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.
Settings