Skip to content
Filipi 2:12-18

Filipi 2:12-18

12
Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì,
13
nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.
14
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.
15
Kí ẹ̀yin lè jẹ́ aláìlẹ́gàn àti oníwà mímọ́, ọmọ Ọlọ́run, aláìlábàwọ́n, láàrín oníwà wíwọ́ àti alárékérekè orílẹ̀-èdè láàrín àwọn ẹni tí a ń rí yín bí ìmọ́lẹ̀ ní ayé.
16
Bí ẹ sì ṣe di ọ̀rọ̀ ìyè mú gírígírí, kí èmi lè ṣògo ni ọjọ́ Kristi pé èmi kò sáré lásán, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ṣe làálàá lásán.
17
Ṣùgbọ́n, bí a tilẹ̀ ń dà mí bí ọtí-ìrúbọ sórí ẹbọ iṣẹ́ ìsìn ìgbàgbọ́ yín, inú mi dùn, mo sì ń bá gbogbo yín yọ̀ pẹ̀lú.
18
Bákan náà ni kí ẹ̀yin máa yọ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀ pẹ̀lú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options