Skip to content
Numeri 26:5-28

Numeri 26:5-28

5
Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá, láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;
6
ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.
7
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).
8
Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu,
9
àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.
10
Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.
11
Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.
12
Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini;
13
ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu.
14
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba (22,200) ọkùnrin.
15
Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;
16
ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri;
17
ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli.
18
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
19
Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.
20
Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera.
21
Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu.
22
Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (76,500).
23
Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa;
24
ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.
25
Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300).
26
Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.
27
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).
28
Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options