Skip to content
Numeri 14:1-12

Numeri 14:1-12

1
Gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbóhùn sókè, wọ́n sì sọkún ní òru ọjọ́ náà.
2
Gbogbo ọmọ Israẹli sì kùn sí Mose àti Aaroni, gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì wí fún wọn pé, “Àwa ìbá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Ejibiti. Tàbí kí a kúkú kú sínú aginjù yìí.
3
Kí ló dé tí Olúwa fi mú wa wá sí ilẹ̀ yìí láti fi idà pa wá? Àwọn ìyàwó wa, àwọn ọmọ wa yóò sì di ìjẹ. Ǹjẹ́ kò wa, ní í dára fún wa bí a bá padà sí Ejibiti?”
4
Wọ́n sì sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí kí á sì padà sí Ejibiti.”
5
Nígbà náà ni Mose àti Aaroni dojúbolẹ̀ níwájú gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli.
6
Joṣua ọmọ Nuni àti Kalebu ọmọ Jefunne, tí wọ́n wà lára àwọn to lọ yẹ ilẹ̀ wò sì fa aṣọ wọn ya.
7
Wọ́n sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a là kọjá láti yẹ̀ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
8
Bí inú Olúwa bá dùn sí wa, yóò mú wa dé ilẹ̀ náà, ilẹ̀ tó ń sàn fún wàrà àti fún oyin, yóò fún wa ní ilẹ̀ náà.
9
Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa. Kí ẹ sì má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ìlú náà, nítorí pé a ó gbé wọn mì, ààbò wọn ti fi wọ́n sílẹ̀, Olúwa sì wà pẹ̀lú àwa, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn.”
10
Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
11
Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo ṣe láàrín wọn?
12
Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options