Nehemiah 1:6-9
6
Jẹ́ kí etí rẹ kí ó ṣí sílẹ̀, kí ojú ù rẹ kí ó sì ṣí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Israẹli. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Israẹli àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.
7
Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ mọ́.
8
“Rántí ìlànà tí o fún Mose ìránṣẹ́ rẹ, wí pé, ‘Bí ìwọ bá jẹ́ aláìṣòótọ́, èmi yóò fọ́n yín ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè.
9
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tilẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’
Settings