Skip to content
Matiu 17:1-13

Matiu 17:1-13

1
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró.
2
Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀.
3
Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀.
4
Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”
5
Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”
6
Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.
7
Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.”
8
Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí.
9
Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.”
10
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?”
11
Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò.
12
Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.”
13
Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options