Marku 13:28-37
28
“Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́, nígbà tí ẹ̀ka rẹ bá ń yọ tuntun, tí ó bá sì ń rú ewé, èyí fihàn pé àkókò ẹ̀rùn ti dé.
29
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ ba ri àwọn ohun wọ̀nyí ti n ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ó súnmọ́ etílé tán, bi ìgbà tí ó wà lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.
30
Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ìran yìí kì yóò rékọjá títí a ó fi mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹ.
31
Ọ̀run àti ayé yóò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi dúró dájú títí ayé àìnípẹ̀kun.
32
“Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀. Àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀. Àní, èmi pẹ̀lú kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe baba nìkan.
33
Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró wámú, kí ẹ sì máa gbàdúrà, nítorí ẹ̀yin kò mọ ìgbà tí àkókò ná yóò dé.
34
Ó dà bí ọkùnrin kan tí ó lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà rere, ẹni tí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, tí ó sì fi àṣẹ fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti iṣẹ́ tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò ṣe, ó sì fi àṣẹ fún ẹni tó dúró lẹ́nu-ọ̀nà láti máa ṣọ́nà.
35
“Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin pẹ̀lú ní láti máa fi ìrètí ṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ àkókò tí baálé ilé yóò dé. Bóyá ní ìrọ̀lẹ́ ni o, tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru, tàbí nígbà tí àkùkọ máa ń kọ, tàbí ní òwúrọ̀.
36
Àti wí pé nígbà tí ó bá dé lójijì, kó má ṣe bá yín lójú oorun.
37
Ohun tí mo wí fún un yín, mo wí fun gbogbo ènìyàn: ‘Ẹ máa ṣọ́nà!’ ”
Settings