Luku 23:50-56
50
Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́.
51
Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run.
52
Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu.
53
Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí.
54
Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀.
55
Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀.
56
Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.
Settings