Fò sí àkóónú
Lefitiku 8:22-30

Àgbò ìsọdimímọ́

Lefitiku 8:22-30
22
Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí.
23
Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni, sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.
24
Mose sì tún mú àwọn ọmọ Aaroni wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.
25
Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún.
26
Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà.
27
Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa.
28
Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa.
29
Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
30
Mose sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ Aaroni àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Mose ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options