Skip to content
Lefitiku 23:26-43

Lefitiku 23:26-43

26
Olúwa sọ fún Mose pé,
27
“Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.
28
Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.
29
Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
30
Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
31
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.
32
Ọjọ́ ìsinmi ni fún un yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsànán oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”
33
Olúwa sọ fún Mose pé,
34
“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.
35
Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.
36
Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá, ní ọjọ́ kẹjọ, ẹ pe ìpàdé mímọ́ kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa, èyí jẹ́ ìpàdé tí ó gbẹ̀yìn; ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojoojúmọ́.
37
(“ ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn àjọ̀dún tí Olúwa ti yàn tí ẹ gbọdọ̀ kéde gẹ́gẹ́ bí i àjọ̀dún tí a yàn fún mímu àwọn ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa wá—ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà, ọrẹ ẹbọ àti ọrẹ ohun mímu, fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
38
Àwọn ọrẹ wọ̀nyí wà ní àfikún pẹ̀lú àwọn ọrẹ ọjọ́ ìsinmi Olúwa, àti pẹ̀lú ẹ̀bùn yín àti ohunkóhun tí ẹ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ àti gbogbo ọrẹ àtinúwá yín fún Olúwa.)
39
“ ‘Torí náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ ti kórè ilẹ̀ náà, ẹ ṣe àjọ̀dún yìí fún Olúwa ní ọjọ́ méje. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ọjọ́ kẹjọ pẹ̀lú si tún jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
40
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, kí ẹ mú àṣàyàn èso láti orí igi dáradára, imọ̀ ọ̀pẹ, àti ẹ̀ka igi tó rúwé, àti igi wílò odò, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín fún ọjọ́ méje.
41
Ẹ ṣe èyí ní àjọ̀dún sí Olúwa fún ọjọ́ méje lọ́dọọdún. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, ẹ ṣe é ní oṣù keje.
42
Ẹ gbé inú àgọ́ fún ọjọ́ méje. Kí gbogbo ọmọ bíbí Israẹli gbé nínú àgọ́.
43
Kí àwọn ìran yín le mọ̀ pé mo mú kí Israẹli gbé nínú àgọ́, nígbà tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options