Lefitiku 18:1-21
1
Olúwa sọ fún Mose pé:
2
“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
3
Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní Ejibiti níbi tí ẹ ti gbé rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe bí wọ́n ti ń ṣe ní ilẹ̀ Kenaani níbi tí èmi ń mú yín lọ. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ìṣe wọn.
4
Kí ẹ̀yin kí ó sì máa ṣe òfin mi, kí ẹ̀yin sì máa pa ìlànà mi mọ́, láti máa rìn nínú wọn, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
5
Ẹ̀yin ó sì máa pa ìlànà mi mọ́ àti òfin mi; Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn. Èmi ni Olúwa.
6
“ ‘Ẹnikẹ́ni nínú yín kò gbọdọ̀ súnmọ́ ìbátan rẹ̀ láti bá a lòpọ̀. Èmí ni Olúwa.
7
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyá rẹ lòpọ̀, ìyá rẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ bá a lòpọ̀.
8
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù baba rẹ nípa bíbá ìyàwó baba rẹ lòpọ̀, nítorí ìhòhò baba rẹ ni.
9
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin rẹ tí ó jẹ́ ọmọ ìyá rẹ lòpọ̀, yálà a bí i nílé yín tàbí lóde.
10
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin, ọmọ rẹ ọkùnrin lòpọ̀ tàbí ọmọbìnrin ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀ nítorí pé ìhòhò wọn, ìhòhò ìwọ fúnra rẹ̀ ni.
11
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin aya baba rẹ lòpọ̀; èyí tí a bí fún baba rẹ nítorí pé arábìnrin rẹ ni.
12
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin baba rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan baba rẹ ni.
13
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá arábìnrin màmá rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan ìyá rẹ ni.
14
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ tàbùkù arákùnrin baba rẹ nípa sísún mọ́ aya rẹ̀ láti bá a lòpọ̀ nítorí pé ìyàwó ẹ̀gbọ́n baba rẹ ni.
15
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọ àna obìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé aya ọmọ rẹ ni. Má ṣe bá a lòpọ̀.
16
“ ‘Má ṣe bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ ọkùnrin lòpọ̀ nítorí pé yóò tàbùkù ẹ̀gbọ́n rẹ.
17
“ ‘Má ṣe bá ìyá àti ọmọ rẹ obìnrin lòpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ bá ọmọbìnrin ọmọkùnrin rẹ tàbí ọmọbìnrin ọmọbìnrin rẹ lòpọ̀ nítorí pé ìbátan rẹ tímọ́tímọ́ ni: nítorí àbùkù ni.
18
“ ‘Má ṣe fẹ́ àbúrò ìyàwó rẹ obìnrin ní aya gẹ́gẹ́ bí orogún tàbí bá a lòpọ̀, nígbà tí ìyàwó rẹ sì wà láààyè.
19
“ ‘Má ṣe súnmọ́ obìnrin láti bá a lòpọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe nǹkan oṣù, nítorí àkókò àìmọ́ ni.
20
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ bá aya aládùúgbò rẹ lòpọ̀, kí ìwọ má ba à ba ara rẹ jẹ́ pẹ̀lú rẹ̀.
21
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ rú ẹbọ lórí pẹpẹ sí òrìṣà Moleki, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings