Ẹkún Jeremiah 3:1-20
1
Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
2
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.
3
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
4
Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
5
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
6
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn, bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
7
Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ; ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
8
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́, ó kọ àdúrà mi.
9
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi; ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.
10
Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀, bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.
11
Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
12
Ó fa ọfà rẹ̀ yọ ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13
Ó fa ọkàn mí ya pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14
Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi; wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15
Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò àti ìdààmú bí omi.
16
Ó ti fi òkúta kán eyín mi; ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17
Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18
Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
19
Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
20
Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
Settings