- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Onidajọ 9:8
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 8 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
5
Ó kó wọn lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, níbẹ̀ ní orí òkúta kan ṣoṣo ni ó ti pa àádọ́rin nínú àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn Jerubbaali, ṣùgbọ́n Jotamu, àbíkẹ́yìn nínú àwọn ọmọ Jerubbaali, bọ́ yọ nítorí pé ó sá pamọ́.
6
Gbogbo àwọn ará Ṣekemu àti àwọn ará Beti-Milo pàdé pọ̀ ní ẹ̀bá igi óákù ní ibi òpó ní Ṣekemu láti fi Abimeleki jẹ ọba.
Àlọ́ Jotamu àti èpè rẹ̀
7
Nígbà tí wọ́n sọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí fún Jotamu, ó gun orí ṣóńṣó òkè Gerisimu lọ, ó sì ké lóhùn rara pé, “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin àgbàgbà Ṣekemu, kí Ọlọ́run le tẹ́tí sí yín.
8
Ní ọjọ́ kan àwọn igi jáde lọ láti fi òróró yan ọba fún ara wọn. Wọ́n pe igi Olifi pé, ‘Wá ṣe ọba wa.’
9
“Ṣùgbọ́n igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Èmi yóò ha fi òróró mi sílẹ̀ èyí tí a ń lò láti fi ọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́run àti ènìyàn kí èmi sì wá ṣe olórí àwọn igi?’
10
“Àwọn igi sọ fún igi ọ̀pọ̀tọ́ pé, ‘Wá jẹ ọba ní orí wa.’
11
“Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Kí èmi fi èso mi tí ó dára tí ó sì dùn sílẹ̀ láti wá ṣe olórí àwọn igi?’
Study this passage
Commentary written on this passage, not on a single verse.
- Who
- Where
- When
- About
Where else Scripture says this.
2 Ọba 14:9
Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì sí Amasiah ọba Juda: “Òṣùṣú kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí kedari ní Lebanoni, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú igbó ní Lebanoni wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.from verse 8Daniẹli 4:10
Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi.from verse 8Daniẹli 4:18
“Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”from verse 8Onidajọ 8:22
Àwọn ará Israẹli wí fún Gideoni pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.”from verse 8Onidajọ 8:23
Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. Olúwa ni yóò jẹ ọba lórí yín.”from verse 8Esekiẹli 17:3
Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi kedari tó ga jùlọ,from verse 8Esekiẹli 17:10
Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”from verse 8


Study Note
Settings