Onidajọ 8:13-21
13
Gideoni ọmọ Joaṣi gba ọ̀nà ìgòkè Heresi padà sẹ́yìn láti ojú ogun.
14
Ó mú ọ̀dọ́mọkùnrin kan ará Sukkoti, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè ní ọwọ́ rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì kọ orúkọ àwọn ìjòyè Sukkoti mẹ́tàdínlọ́gọ́rin fún un tí wọ́n jẹ́ àgbàgbà ìlú náà.
15
Nígbà náà ni Gideoni wá ó sọ fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Seba àti Salmunna nìwọ̀nyí nípa àwọn tí ẹ̀yin fi mí ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ẹ wí pé, ‘Ṣé ó ti ṣẹ́gun Seba àti Salmunna? Èéṣe tí àwa ó fi fún àwọn ọmọ-ogun rẹ tí ó ti rẹ̀ ní oúnjẹ?’ ”
16
Ó mú àwọn àgbàgbà ìlú náà, ó sì fi kọ́ àwọn Sukkoti lọ́gbọ́n nípa jíjẹ wọ́n ní yà pẹ̀lú àwọn ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún ọ̀gàn.
17
Ó wó ilé ìṣọ́ Penieli, ó sì pa àwọn ọkùnrin ìlú náà.
18
Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.
19
Gideoni dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi Olúwa búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò nípa yín.”
20
Ó yí padà sí Jeteri, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jeteri kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.
21
Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
Settings