Skip to content
Onidajọ 2:11-19

Onidajọ 2:11-19

11
Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Baali.
12
Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀, ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíríṣìí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú,
13
nítorí tí wọ́n kọ̀ Olúwa sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ń sin Baali àti Aṣtoreti.
14
Nínú ìbínú rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli Olúwa fi wọ́n lé àwọn akónisìn lọ́wọ́ tí ó kó wọn ní ẹrú, tí ó sì bà wọ́n jẹ́. Ó sì tà wọ́n fún àwọn ọ̀tá wọn tí ó yí wọn ká àwọn ẹni tí wọn kò le dúró dè láti kọ ojú ìjà sí.
15
Nígbàkígbà tí àwọn Israẹli bá jáde lọ sí ojú ogun láti jà, ọwọ́ Olúwa sì wúwo ní ara wọn, àwọn ọ̀tá a sì borí wọn, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti búra fún wọn. Wọ́n sì wà nínú ìpọ́njú púpọ̀.
16
Olúwa sì gbé àwọn onídàájọ́ dìde tí ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ń kó wọn lẹ́rú.
17
Síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò fi etí sí ti àwọn onídàájọ́ wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n ń sin òrìṣà. Wọn kò dàbí àwọn baba wọn, kíákíá ni wọ́n yípadà kúrò lọ́nà tí àwọn baba wọ́n ń tọ̀, ọ̀nà ìgbọ́ràn sí àwọn òfin Olúwa.
18
Nígbà kí ìgbà tí Olúwa bá gbé onídàájọ́ dìde fún wọn, Olúwa máa ń wà pẹ̀lú onídàájọ́ náà, a sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn ní ìwọ̀n ìgbà tí onídàájọ́ náà bá wà láààyè nítorí àánú Olúwa wà ní ara wọn, nígbà tí wọ́n bá ké ìrora lábẹ́ àwọn tí ń tẹrí wọn ba, tí sì ń fi ìyà jẹ wọ́n.
19
Ṣùgbọ́n ní kété tí onídàájọ́ bá ti kú, àwọn ènìyàn náà a sì tún padà sí ọ̀nà ìbàjẹ́ àní ju ti àwọn baba wọn lọ, wọn a tẹ̀lé òrìṣà, wọ́n ń sìn wọ́n, wọn a sì foríbalẹ̀ fún wọn, wọ́n kọ̀ láti yàgò kúrò ní ọ̀nà ibi wọn àti agídí ọkàn wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options