Skip to content
Joṣua 8:1-8

Joṣua 8:1-8

1
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù, kí àyà kí ó má ṣe fò ọ́. Kó gbogbo àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ, kí ẹ gòkè lọ gbógun ti Ai. Nítorí mo ti fi ọba Ai, àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú u rẹ̀ àti ilẹ̀ ẹ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́.
2
Ìwọ yóò sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, ohun ìkógun wọn àti ohun ọ̀sìn wọn ni kí ẹ̀yin mú fún ara yín. Rán ènìyàn kí wọ́n ba sí ẹ̀yìn ìlú náà.”
3
Bẹ́ẹ̀ ní Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun jáde lọ láti dojúkọ Ai. Ó sì yan ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (30,000) àwọn ọkùnrin ogun rẹ̀ ti ó yakin, ó sì rán wọn lọ ní òru.
4
Pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí: “Ẹ fi etí sílẹ̀ dáradára. Ẹ ba sí ẹ̀yìn ìlú náà. Ẹ má ṣe jìnnà sí i púpọ̀. Kí gbogbo yín wà ní ìmúrasílẹ̀.
5
Èmi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi yóò súnmọ́ ìlú náà, nígbà tí àwọn ọkùnrin náà bá jáde sí wa, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìṣáájú, àwa yóò sì sá kúrò níwájú u wọn.
6
Wọn yóò sì lépa wa títí àwa ó fi tàn wọ́n jáde kúrò ní ìlú náà, nítorí tí wọn yóò wí pé, wọ́n ń sálọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ṣe ní ìṣáájú. Nítorí náà bí a bá sá kúrò fún wọn,
7
ẹ̀yin yóò dìde kúrò ní ibùba, ẹ ó sì gba ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run yín yóò sì fi lé e yín lọ́wọ́.
8
Nígbà tí ẹ bá ti gba ìlú náà, kí ẹ sì ti iná bọ̀ ọ́. Kí ẹ ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ. Mo ti fi àṣẹ fún un yín ná.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options