Skip to content
Joṣua 3:7

Joṣua 3:7

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 7 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
4
Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárín yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́.”
5
Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”
6
Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.
7
Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Òní yìí ni Èmi yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ọ ga ní ojú u gbogbo àwọn ará Israẹli, kí wọn lè mọ̀ pé Èmi wà pẹ̀lú rẹ gẹ́gẹ́ bí mo ṣe wà pẹ̀lú Mose.
8
Sọ fún àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí náà, ‘Nígbà tí ẹ bá dé etí omi Jordani, ẹ lọ kí ẹ sì dúró nínú odò náà.’ ”
9
Joṣua sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ súnmọ́ ibí kí ẹ̀yin kí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run yín.
10
Èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Ọlọ́run alààyè wà ní àárín yín àti pé dájúdájú yóò lé àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, Hifi, Peresi, Girgaṣi, Amori àti Jebusi jáde níwájú u yín.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options