Joṣua 3:1-6
1
Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, Joṣua àti gbogbo àwọn Israẹli sí kúrò ní Ṣittimu, wọ́n sì lọ sí etí odò Jordani, wọ́n sì pa ibùdó síbẹ̀ kí wọn tó kọjá.
2
Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta àwọn olórí la àárín ibùdó já.
3
Wọ́n sì pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Nígbà tí ẹ bá rí àpótí ẹ̀rí Olúwa Ọlọ́run yín, tí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi rù ú, nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sí kúrò ní ipò yín, ẹ̀yin yóò sì máa tẹ̀lé e.
4
Ẹyin yóò lè mọ ọ̀nà tí ẹ ó gbà, torí pé ẹ̀yin kò gba ọ̀nà yìí tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n àlàfo gbọdọ̀ wà ní àárín yín àti àpótí náà, tó bí ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ìgbọ̀nwọ́.”
5
Joṣua sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ya ara yín sí mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Olúwa yóò ṣe ohun ìyanu ní àárín yín.”
6
Joṣua sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ̀yin, ẹ gbé àpótí ẹ̀rí náà kí ẹ̀yin kí ó sì máa lọ ṣáájú àwọn ènìyàn.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé e sókè, wọ́n sì ń lọ ní iwájú u wọn.
Settings