Skip to content
Joṣua 22:17-20

Joṣua 22:17-20

17
Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn Olúwa!
18
Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí? “ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli.
19
Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa.
20
Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options