Joṣua 11:12-15
12
Joṣua sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ.
13
Síbẹ̀ Israẹli kò sun ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kéékèèké, àyàfi Hasori nìkan tí Joṣua sun.
14
Àwọn ará Israẹli sì kó gbogbo ìkógun àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátápátá, kò sí ẹni tí ó wà láààyè.
15
Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.
Settings