Joṣua 10:38-43
38
Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ yí padà, wọ́n sì kọlu Debiri.
39
Wọ́n gba ìlú náà, ọba rẹ̀ àti gbogbo ìlú wọn, wọ́n sì fi idà pa wọ́n. Gbogbo ènìyàn inú rẹ̀ ni wọ́n parun pátápátá. Wọn kò sì dá ẹnìkankan sí. Wọ́n ṣe sí Debiri àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọn ti ṣe sí Libina àti ọba rẹ̀ àti sí Hebroni.
40
Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣẹ́gun gbogbo agbègbè náà, ìlú òkè, gúúsù, ìlú ẹsẹ̀ òkè ti ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè pẹ̀lú gbogbo ọba, wọn kò dá ẹnìkankan sí. Ó pa gbogbo ohun alààyè run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ti pàṣẹ.
41
Joṣua sì ṣẹ́gun wọn láti Kadeṣi-Barnea sí Gasa àti láti gbogbo agbègbè Goṣeni lọ sí Gibeoni.
42
Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí àti ilẹ̀ wọn ní Joṣua ṣẹ́gun ní ìwọ́de ogun ẹ̀ẹ̀kan, nítorí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, jà fún Israẹli.
43
Nígbà náà ni Joṣua padà sí ibùdó ní Gilgali pẹ̀lú gbogbo Israẹli.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings