Joṣua 10:1-4
1
Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.
2
Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun.
3
Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,
4
“Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”
Settings