Přejít k obsahu
Johanu 20:26-31

Johanu 20:26-31

26
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.”
27
Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”
28
Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”
29
Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́, alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”
30
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí.
31
Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options